Oriki of Odumosu Clan
By Super Admin • 22 viewsOmo Ita Ntebo Alabameji
Omo Ita Ntebo Madasa
Omo Tangba-Tangba; o fi igba nla moti
O fi Awo nla je’gbin
Ara Iyanro Oginnu Omo
Omo Eweje Elewu Odo
Omo Elewu woyi woyi
O wo dudu, O wo funfun
O wo Alari lojo ale
Omo Apebi Logere
O kole si Mose, O rodede si Mogun
T’ori keji ma pa Iseji Orun
Omo Agbade loba lori
Omo ogidan nwe lodo, gbogbo omoge
Nyowo ose, nwon ni gba temi gba temi
Eni to gba tire lo sorire.